Àwọn wòlíì ti máa ń pa ìtàn ìran mọ́ nígbà gbogbo.
Ó sì ṣe pé bàbá mi, Léhì, tún rí ìtàn ìdílé àwọn bàbá rẹ̀ lórí àwọn àwo idẹ nã; nítorí-èyi ó mọ̀ wí pé òun jẹ́ àtẹ̀lé Jósẹ́fù; bẹ̃ ni, àní Jósẹ́fù nì, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ Jákọ́bù, ẹni tí a tà sí Égíptì, ẹni tí a sì pamọ́ nípa ọwọ́ Olúwa, kí ó lè ṣe ìpamọ́ bàbá rẹ̀, Jákọ́bù, àti gbogbo agbolé rẹ̀ kúrò nínú ṣíṣègbé pẹ̀lú ìyàn.
Léhì rí ìtàn ìran rẹ̀ nínú àwọn àwo idẹ, ó sì mọ̀ pé láti ìran Jósẹ́fù ti Íjíbítì ni òun ti wá.
Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ọmọ mi, mo fẹ́ kí ẹ̀yin ó rántí láti pa òfin Ọlọ́run mọ́; èmi sì fẹ́ kí ẹ̀yin ó kéde àwọn ọ̀rọ̀ yĩ fún àwọn ènìyàn. Ẹ̀ kíyèsĩ, èmi ti fún nyín ní orúkọ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ tí nwọn jáde wa láti ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù; mo sì ṣe èléyĩ pé nígbàtí ẹ̀yin ó bá rántí orúkọ nyín pé ẹ̀yin ó lè rántí nwọn; tí ẹ̀yin bá sì rántí nwọn ẹ̀yin yiò rántí àwọn iṣẹ́ nwọn; nígbàtí ẹ̀yin bá sì rántí àwọn iṣẹ́ nwọn ẹ̀yin yíò mọ̀ pé a ti sọọ́, a sì ti kọọ́, pé nwọ́n dára.
Hẹ́lámánì sọ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní orúkọ àwọn baba ńlá olódodo, kí rírántí orúkọ wọn lè rán wọn létí ìwà rere àwọn baba ńlá wọn.
Nísisìyí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ni Ádámù sọ, bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe dárí rẹ̀, a sì ṣe ìpamọ́ ìtàn ìrandíran ti àwọn ọmọ Ọlọ́run. Èyí sì ni ìwé ìtàn àwọn ìrandíran ti Ádámù, wípé: Ní ọjọ́ tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní ìrí ti Ọlọ́run ni ó dá a;
Láti ìgbà Ádámù ni a ti pa ìtàn ìran àwọn ọmọ Ọlọ́run mọ́, àkọsílẹ̀ ẹbí àkọ́kọ́ tí a kọ sílẹ̀.
Ṣùgbọ́n àwọn àkọsílẹ̀ ti àwọn baba, àní àwọn pátríákì, nípa ẹ̀tọ́ ti Oyè Àlùfáà, ni Olúwa Ọlọ́run mi pa mọ́ sí ọwọ́ mi; nítorínáà ìmọ̀ ti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá, àti bákannáà ti àwọn ohun tí nyípo oòrun, àti ti àwọn ìràwọ̀, bí a ṣe sọ wọ́n di mímọ̀ fún àwọn baba, ni èmi ti pamọ́ àní titi di òní yìí, èmi yíò sì gbìyànjú láti kọ díẹ̀ nínú àwọn ohun wọ̀nyí sí orí àkọsílẹ̀ yìí, fún ànfààní ti irú ọmọ mi tí yíò wá lẹ́hìn mi.
Ábráhámù pa àwọn àkọsílẹ̀ àwọn baba rẹ̀ mọ́, ó sì kọ̀wé fún àǹfààní àwọn ìran rẹ̀.

Èmi ìbá ṣe ìtúmọ̀ kan tí ó ṣe kedere jù sí èyí, ṣùgbọ́n ó ṣe kedere tó láti mú yẹ fún èrò mi bí ó ṣe dúró. Ó tó láti mọ̀, nínú ọ̀rọ̀ yìí, pé a ó kọlu ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ègún bìkòṣepé irú àsopọ̀ kan tàbí òmíràn wà láàrin àwọn baba àti àwọn ọmọ, ní orí àwọn àkòrí kan tàbí òmíràn—sì kíyèsíi kínni àkòrí náà? Òun ni ìrìbọmi fún àwọn òkú. Nítorí àwa láìsí àwọn a kì yíò lè sọ wá di pípé; bẹ́ẹ̀ a kì yío le sọ àwọn láìsí àwa di pípé. Bẹ́ẹ̀ a kì yío lè sọ àwọn tàbí àwa di pípé láì sí àwọn tí wọ́n ti kú nínú ìhìnrere bákannáà; nítorí ó ṣe pàtàkì ní gbígbà wọlé ti ìgbà ìríjú ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò, ìgbà ìríjú náà èyítí ó bẹ̀rẹ̀ nísìsìyìí láti jẹ́ gbígbà wọlé, pé kí odidi àti tí ó pé àti ìdàpọ̀ dídára, àti àsopọ̀ àwọn ìgbà ìríjú, àti àwọn kọ́kọ́rọ́, àti àwọn agbára, àti àwọn ògo yíò ṣẹlẹ̀, tí a ó sì fihàn láti àwọn ọjọ́ ti Ádámù àní sí àkókò tí a wà yìí. Kìí sì ṣe èyí nìkan, ṣùgbọ́n àwọn ohun wọnnì èyítí a kò tíì fi hàn rí láti ìpìlẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a ti fi pamọ́ sí ìkọ̀kọ̀ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti olóye, yíò di fífihàn sí àwọn ọmọ ọwọ́ àti àwọn ọmọ ọmú nínú èyí, ìgbà ìríjú ti ẹ̀kúnrẹrẹ àwọn àkókò.
Iṣẹ́ fún àwọn òkú ni “àsopọ̀” tí ó ń so àwọn ìran pọ̀ sí ìṣọ̀kan pípé kan.
Ẹ̀yin arákùrin, àwa kì yíò ha tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ títóbi bẹ́ẹ̀? Ẹ tẹ̀síwájú kìí sì í ṣe sẹ́hìn. Ìgboyà, ẹ̀yin arákùnrin; ẹ sì tẹ̀síwájú, síwájú sí ìṣẹ́gun! Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín kí ó yọ̀, kí ẹ sì dunnú gidigidi. Ẹ jẹ́kí ilẹ̀ ayé kí ó bú jáde sí orin kíkọ. Ẹ jẹ́kí àwọn òkú kí ó sọ àwọn orin àdákọ ti ìyìn ayérayé sí Ọba Ìmmanúẹ́lì, ẹnití ó ti yàn, kí ayé ó tó wà, èyí tí yíò mú wa láti rà wọ́n padà jade láti inú túbú wọn; nítorí àwọn ará túbú yíò lọ ní òmìnira.
Ìpè ayọ̀ Joseph Smith láti tẹ̀síwájú nínú ríra àwọn òkú padà, nítorí àwọn ará túbú yóò lọ ní òmìnira.
Kíyèsíi, ọjọ́ nlá Olúwa náà kù sí dẹ̀dẹ̀; taani ó sì lè fi ara da ọjọ́ bíbọ̀ rẹ̀, àti taani ó lè dúró nígbàtí òun bá fi ara hàn? Nítorí òun dàbí iná ayọ́rin, àti bí ọṣẹ afọṣọ; òun yíò sì jókòó bí ẹnití nyọ́ àti tí ó nda fàdákà, òun yíò sì sọ àwọn ọmọ Léfì di mímọ́, yío sì jọ̀ wọ́n mọ́ bí wúrà àti fàdákà, kí wọn kí ó lè rú ẹbọ sí Olúwa ẹbọ-ọrẹ kan nínú òdodo. Ẹ jẹ́kí àwa, nítorínáà, bí ìjọ kan àti àwọn ènìyàn kan, àti bí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, rú ẹbọ sí Olúwa ẹbọ-ọrẹ kan nínú òdodo; ẹ sì jẹ́kí a gbé e kalẹ̀ nínú tẹ́mpìlì mímọ́ rẹ̀, nígbàtí ó bá parí, ìwé kan tí ó ní àwọn àkọsílẹ̀ ti àwọn òkú wa nínú, èyítí yíò jẹ́ yíyẹ fún gbogbo ìtẹ́wọ́gbà.
A pe àwọn Ènìyàn Mímọ́ láti gbé ìwé tí ó yẹ, tí ó ní àwọn àkọsílẹ̀ àwọn òkú wọn nínú, kalẹ̀ nínú tẹ́mpìlì.